Yetunde S. Alabede

Yetunde S. Alabede
Yétúndé S. Alábẹdé jẹ́ ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Ògùn ṣùgbón ̣ ό d'àgbà sí Ìpínlẹ̀Èkó ní Nàìjíríà. Èdè Yorùbá jẹ́ èdè abínibí rẹ. Ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ìwé gíga ìlú Michigan tí ó wà ní àdúgbò ìlà oòrùn Lansing. Ó ń k'ẹ́kọ̀ọ́ láti di ọ̀mọ̀wé nínú ìmọ̀ k'íkọ́ni l'ẹ́kọ̀ọ́ oríṣiríṣi èdè. Ó ń ṣe ìwádìí nípa oríṣiríṣi lílo èdè abínibí àti èdè àdúgbò láàrín àwọn ẹbí àtọ̀únrìnwá pẹ̀ lú ipa náà lórí èdè tí àwọn ọmọ wọn ń sọ. Bákan náà, ό ń ṣe ìwádìí lórí bí àwọn olùkọ́ṣe ń gbímọ̀pọ̀ṣiṣẹ́ pẹlu èdè àwọn ọmọ tí wọn ń sọ èdè tí ó yàtọ̀sí èdè òyìnbó. Kí ό tóó wá sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga Michigan, ό jẹ́ olùkọ́ èdè Yorùbá, èdè òyìnbó àti Mandarin fún àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ K-12 ní ìpínlè Èkó ni Nàìjíríà fún bí ọdún méwàá ̣ . Lẹ́yìn náà, ό kọ́ èdè Yorùbá gẹ́gẹ́bí akẹgbẹ́ Fulbright ni Fayetteville State University ni North Carolina fún oṣù mẹ́sàn kí ό tó wá lọ kẹ́kọ̀ọ́ gb'oyè nípa Cross-cultural àti International Education ni Bowling Green State University ní ìlú Ohio. Yétúndé fẹ́ràn láti máa se oúnjẹ àti láti máa rìn. Ère ìdárayà tí ό nífẹ̀ẹ́sí ni ère sísá. Lẹ́yìn ìrẹsì jọ̀ lọ́fù àti dòdò, oúnje àwọn ará Amẹ́ríkà tí ό féràn jù ni Cheeseburger. Kò féràn òtútù bó tilẹ̀ jẹ́ pé Michigan máa ń tutù púpọ́ ní Winter. Ẹ ṣeun.
  • Bio in English

    Yetunde S. Alabede is originally from Ogun state but grew up in Lagos, Nigeria. Yorùbá is her native language. She is a Doctoral Student in Curriculum, Instruction, and Teacher Education (CITE) with research interests in bi/multilingual education. Her research examines language practice and uses among transnational families. Additionally, she researches how teachers work closely with bi/multilingual children in an asset-based approach. Before coming to Michigan State University (MSU), she taught Yorùbá language, English, and Chinese Mandarin to K-12 students for about ten years in Lagos, Nigeria. Afterward, she taught Yorùbá language as a Fulbright fellow at Fayetteville State University, North Carolina, for nine months before completing her master's degree in Crosscultural and International Education (MACIE) at Bowling Green State University (BGSU), Ohio. Yetunde loves cooking and going for a walk. Her favorite sport is track and field (relay). Apart from rice and fried plantain, her favorite American food is Cheeseburger. She does not like cold, even though Michigan is always cold in Winter.